Awelewa mi owon, temi ni tire
Ayo Okan Mi, Temi Ni Tire
Bi Adanwo Ife Bade, Temi Ni Tire
Bi Ojumo Bamo, Temi Ni Tire
Bi O Wa Ni Ila-orun, Temi Ni Tire
Ekuro Lalaba Ku Ewa Emi Ati Iwo Nitori, Temi Ni Tire,
Nigbati Mo N Saare, Temi Ni Tire
Nigbati Ohun Saare, Temi Ni Tire
Nigbati Mo Se Aferi Re, Temi Ni Tire
Nigbati Ohun Se Aferi Mi, Temi Ni Tire
Nigbati Odun, Temi Ni Tire
Nigbati Ija Wa, Temi Ni Tire
Ninu Oko Ife Yi, Temi Ni Tire
Ninu Wahala Aiye Yi, Temi Ni Tire
Ninu Ina Ife Ti Ohun Jo Yi, Temi Ni Tire
Ninu Odo Ife Ti O Kun Yi, Temi Ni Tire
Ninu Orun Ayo Ti O Ran Yi, Temi Ni Tire
Ninu Osupa Ife Ti Yoo Yi, Temi Ni Tire
Ninu Otalenigba Obinrin To Wa Laiye Yi, Temi Ni Tire
Ninu Edegberin Arewa Won Yi, Temi Ni Tire
Ninu Irinajo Aiye Won Yi, Temi Ni Tire
Ti Mo Wa Ni Iwo-orun, Temi Ni Tire
Ti Igbin Ni Ikaraun, Temi Ni Tire
Ti Agbe Ni Aro, Temi Ni Tire
Ti Aluko Ni Osun, Temi Ni Tire
Ti Okin Ni Ade, Temi Ni Tire
Ti Egbin Ni Ewa, Temi Ni Tire
Ti Lekeleke Ni Efun, Temi Ni Tire
Ti Nini Ni Aran, Temi Ni Tire… (PTO)

Ti Teteopopo Ni Titu Minijojo Temi Ni Tire
Ti Orun Lo Ni Ojo, Temi Ni Tire
Ti Osupa Lo Ni Oru, Temi Ni Tire
Ti Alabe Lo Ni Irun Ori, Temi Ni Tire
Ti Eja Lo Ni Ebu, Temi Ni Tire
Ti Omuwe Lo Ni Odo, Temi Ni Tire
Ti Oba Ni Ade Ati Irukere, Temi Ni Tire
Ti Oloye Ni Ileke, Temi Ni Tire
Ti Ojoori Ni Igba, Temi Ni Tire
Ti Igi Ni Afomo, Temi Ni Tire
Ti Iyo Ni Adun, Temi Ni Tire
Titi Aye Ainipekun, Temi Ni Tire
Titi Iku Yo Fi Yawa, Temi Ni Tire
Temi Ni Tire Nitoto Nitor Tire Ni Temi

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here